-
2 Àwọn Ọba 9:7-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Kí o pa àwọn ará ilé Áhábù olúwa rẹ, màá sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì àti ti gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà tí Jésíbẹ́lì pa.+ 8 Gbogbo ilé Áhábù ló máa ṣègbé; màá sì pa gbogbo ọkùnrin* ilé Áhábù run, títí kan àwọn aláìní àti àwọn aláìníláárí ní Ísírẹ́lì.+ 9 Màá ṣe ilé Áhábù bí ilé Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì àti bí ilé Bááṣà+ ọmọ Áhíjà.
-