-
1 Àwọn Ọba 2:10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Lẹ́yìn náà, Dáfídì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí Ìlú Dáfídì.+
-
-
2 Kíróníkà 21:18-20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Lẹ́yìn gbogbo èyí, Jèhófà fi àìsàn kan tí kò ṣeé wò sàn kọ lù ú ní ìfun rẹ̀.+ 19 Nígbà tó yá, tí ọdún méjì gbáko ti kọjá, ìfun rẹ̀ tú jáde nítorí àìsàn tó ń ṣe é, ó sì kú nínú ìrora ńlá tí àìsàn náà mú bá a; àwọn èèyàn rẹ̀ kò ṣe ìfinásun nítorí rẹ̀ bí wọ́n ti ṣe ìfinásun nítorí àwọn baba ńlá rẹ̀.+ 20 Ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n (32) ni nígbà tó jọba, ọdún mẹ́jọ ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Kò sẹ́ni tí ikú rẹ̀ dùn. Torí náà, wọ́n sin ín sí Ìlú Dáfídì,+ àmọ́ kì í ṣe ní ibi tí wọ́n sin àwọn ọba sí.+
-