33 Mósè fún àwọn ọmọ Gádì, àwọn ọmọ Rúbẹ́nì+ àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè+ ọmọ Jósẹ́fù ní ilẹ̀ tí Síhónì+ ọba àwọn Ámórì ti ń jọba àti ilẹ̀ ti Ógù+ ọba Báṣánì ti ń jọba, ilẹ̀ tó wà láwọn ìlú rẹ̀ ní àwọn agbègbè yẹn àti àwọn ìlú tó yí ilẹ̀ náà ká.
9 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù, ní Ṣílò, ní ilẹ̀ Kénáánì, wọ́n sì pa dà sí ilẹ̀ Gílíádì,+ ilẹ̀ tí wọ́n jogún tí wọ́n sì ń gbé bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ nípasẹ̀ Mósè.+