-
Àìsáyà 36:13-20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Rábúṣákè bá dìde, ó gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì fi èdè àwọn Júù sọ̀rọ̀,+ ó ní: “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba ńlá, ọba Ásíríà.+ 14 Ohun tí ọba sọ nìyí, ‘Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hẹsikáyà tàn yín jẹ, nítorí kò lè gbà yín sílẹ̀.+ 15 Ẹ má sì jẹ́ kí Hẹsikáyà mú kí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà,+ bó ṣe ń sọ pé: “Ó dájú pé Jèhófà máa gbà wá, a ò sì ní fi ìlú yìí lé ọba Ásíríà lọ́wọ́.” 16 Ẹ má fetí sí Hẹsikáyà, torí ohun tí ọba Ásíríà sọ nìyí: “Ẹ bá mi ṣe àdéhùn àlàáfíà, kí ẹ sì túúbá,* kálukú yín á máa jẹ látinú àjàrà rẹ̀ àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, á sì máa mu omi látinú kòtò omi rẹ̀, 17 títí màá fi wá kó yín lọ sí ilẹ̀ tó dà bí ilẹ̀ yín,+ ilẹ̀ ọkà àti ti wáìnì tuntun, ilẹ̀ oúnjẹ àti ti àwọn ọgbà àjàrà. 18 Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hẹsikáyà ṣì yín lọ́nà bó ṣe ń sọ pé, ‘Jèhófà máa gbà wá.’ Ǹjẹ́ ìkankan lára ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè ti gba ilẹ̀ wọn kúrò lọ́wọ́ ọba Ásíríà?+ 19 Ibo ni àwọn ọlọ́run Hámátì àti ti Áápádì+ wà? Ibo ni àwọn ọlọ́run Séfáfáímù+ wà? Ǹjẹ́ wọ́n gba Samáríà kúrò lọ́wọ́ mi?+ 20 Èwo nínú gbogbo ọlọ́run àwọn ilẹ̀ yìí ló ti gba ilẹ̀ wọn kúrò lọ́wọ́ mi, tí Jèhófà yóò fi gba Jerúsálẹ́mù kúrò lọ́wọ́ mi?”’”+
-