-
2 Àwọn Ọba 19:17-19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Jèhófà, òótọ́ ni pé àwọn ọba Ásíríà ti pa àwọn orílẹ̀-èdè àti ilẹ̀ wọn run.+ 18 Wọ́n sì ti ju àwọn ọlọ́run wọn sínú iná, nítorí wọn kì í ṣe ọlọ́run,+ iṣẹ́ ọwọ́ èèyàn ni wọ́n,+ wọ́n jẹ́ igi àti òkúta. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi lè pa wọ́n run. 19 Àmọ́ ní báyìí, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run wa, jọ̀ọ́ gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀, kí gbogbo ìjọba ayé lè mọ̀ pé ìwọ Jèhófà nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run.”+
-