-
2 Àwọn Ọba 21:16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Mánásè ta ẹ̀jẹ̀ àwọn aláìṣẹ̀ sílẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ débi pé ó kún Jerúsálẹ́mù láti ìkángun kan dé ìkángun kejì,+ yàtọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ èyí tí ó mú Júdà ṣẹ̀, tí wọ́n fi ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà.
-
-
2 Àwọn Ọba 23:26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Síbẹ̀, Jèhófà kò dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ tó ń jó bí iná lórí Júdà nítorí gbogbo ohun búburú tí Mánásè ti ṣe láti mú un bínú.+
-
-
2 Kíróníkà 33:11-13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Nítorí náà, Jèhófà mú kí àwọn olórí ọmọ ogun ọba Ásíríà wá gbéjà kò wọ́n, wọ́n fi ìwọ̀ mú Mánásè,* wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà méjì dè é, wọ́n sì mú un lọ sí Bábílónì. 12 Nínú ìdààmú tó bá a, ó bẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ pé kó ṣíjú àánú wo òun,* ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gidigidi níwájú Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ̀. 13 Ó ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sì mú kí àánú ṣe Ọlọ́run, ó gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ fún ojú rere, ó sì mú un pa dà sí Jerúsálẹ́mù sí ipò ọba rẹ̀.+ Mánásè sì wá mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́.+
-