-
Diutarónómì 12:30, 31Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 rí i pé o ò kó sí ìdẹkùn lẹ́yìn tí wọ́n bá pa run kúrò níwájú rẹ. Má ṣe béèrè nípa àwọn ọlọ́run wọn pé, ‘Báwo ni àwọn orílẹ̀-èdè yìí ṣe máa ń sin àwọn ọlọ́run wọn? Ohun tí wọ́n ṣe lèmi náà máa ṣe.’+ 31 O ò gbọ́dọ̀ ṣe báyìí sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ, torí gbogbo ohun tí Jèhófà kórìíra ni wọ́n máa ń ṣe sí àwọn ọlọ́run wọn, kódà wọ́n máa ń sun àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn nínú iná sí àwọn ọlọ́run wọn.+
-
-
2 Kíróníkà 36:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Gbogbo olórí àwọn àlùfáà àti àwọn èèyàn náà hùwà àìṣòótọ́ tó bùáyà, wọ́n ń ṣe àwọn ohun ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè ń ṣe, wọ́n sì sọ ilé Jèhófà di ẹlẹ́gbin,+ èyí tó ti yà sí mímọ́ ní Jerúsálẹ́mù.
-