-
Léfítíkù 18:3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe bí wọ́n ṣe ń ṣe nílẹ̀ Íjíbítì tí ẹ gbé rí, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ ṣe bí wọ́n ṣe ń ṣe nílẹ̀ Kénáánì tí mò ń mú yín lọ.+ Ẹ ò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àṣẹ wọn.
-
-
Léfítíkù 20:2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹ gbọ́dọ̀ pa ọmọ Ísírẹ́lì àti àjèjì èyíkéyìí tó ń gbé ní Ísírẹ́lì tó bá fún Mólékì ní ìkankan nínú àwọn ọmọ rẹ̀.+ Kí àwọn èèyàn ilẹ̀ náà sọ ọ́ lókùúta pa.
-
-
Diutarónómì 18:10-12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Ẹnì kankan láàárín yín ò gbọ́dọ̀ sun ọmọkùnrin rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ nínú iná,+ kò gbọ́dọ̀ woṣẹ́,+ kò gbọ́dọ̀ pidán,+ kò gbọ́dọ̀ wá àmì ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀,+ kò gbọ́dọ̀ di oṣó,+ 11 kò gbọ́dọ̀ fi èèdì di àwọn ẹlòmíì, kò gbọ́dọ̀ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò+ tàbí woṣẹ́woṣẹ́,+ kò sì gbọ́dọ̀ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ òkú.+ 12 Torí Jèhófà kórìíra ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, torí àwọn ohun ìríra yìí sì ni Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe máa lé wọn kúrò níwájú yín.
-