-
Jeremáyà 21:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Jeremáyà gbọ́ ọ̀rọ̀ látọ̀dọ̀ Jèhófà, nígbà tí Ọba Sedekáyà+ rán Páṣúrì+ ọmọ Málíkíjà àti Sefanáyà+ ọmọ Maaseáyà, àlùfáà sí i, pé: 2 “Jọ̀wọ́ bá wa wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, torí pé Nebukadinésárì* ọba Bábílónì ń bá wa jà.+ Bóyá Jèhófà á ṣe ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ àrà rẹ̀ nítorí wa, kí ọba yìí lè pa dà lẹ́yìn wa.”+
-
-
Jeremáyà 29:25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ nìyí: “Nítorí pé o fi àwọn lẹ́tà ránṣẹ́ ní orúkọ rẹ sí gbogbo àwọn èèyàn tó wà ní Jerúsálẹ́mù àti sí Sefanáyà+ ọmọ Maaseáyà tó jẹ́ àlùfáà àti sí gbogbo àwọn àlùfáà, pé,
-
-
Jeremáyà 29:29Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 Nígbà tí àlùfáà Sefanáyà+ ka lẹ́tà yìí létí wòlíì Jeremáyà,
-