9 Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Yútíkọ́sì jókòó sójú fèrèsé, ó sùn lọ fọnfọn nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, oorun ti gbé e lọ, ló bá ṣubú láti àjà kẹta, ó sì ti kú nígbà tí wọ́n fi máa gbé e. 10 Àmọ́ Pọ́ọ̀lù lọ sísàlẹ̀, ó dùbúlẹ̀ lé e, ó sì gbá a mọ́ra,+ ó sọ pé: “Ẹ dákẹ́ ariwo, torí ó ti jí.”+