-
1 Sámúẹ́lì 6:21-7:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Ìgbà náà ni wọ́n rán àwọn òjíṣẹ́ sí àwọn tó ń gbé ní Kiriati-jéárímù+ pé: “Àwọn Filísínì ti dá Àpótí Jèhófà pa dà o. Ẹ wá gbé e lọ sọ́dọ̀ yín.”+
7 Nítorí náà, àwọn ọkùnrin Kiriati-jéárímù wá, wọ́n gbé Àpótí Jèhófà lọ sí ilé Ábínádábù+ tó wà lórí òkè, wọ́n sì ya Élíásárì ọmọ rẹ̀ sí mímọ́ láti máa ṣọ́ Àpótí Jèhófà.
-
-
2 Sámúẹ́lì 6:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Dáfídì tún kó gbogbo àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì tó jẹ́ akọni jọ, wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ (30,000) ọkùnrin. 2 Dáfídì àti gbogbo àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ bá lọ sí Baale-júdà kí wọ́n lè gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́+ wá láti ibẹ̀, iwájú rẹ̀ ni àwọn èèyàn ti ń ké pe orúkọ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,+ ẹni tó ń jókòó lórí* àwọn kérúbù.+
-
-
1 Kíróníkà 15:3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Lẹ́yìn náà, Dáfídì pe gbogbo Ísírẹ́lì jọ sí Jerúsálẹ́mù láti gbé Àpótí Jèhófà wá sí ibi tí ó ti ṣètò sílẹ̀ fún un.+
-