-
1 Sámúẹ́lì 27:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Dáfídì máa ń jáde lọ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin rẹ̀ kí wọ́n lè kó nǹkan àwọn ará Géṣúrì+ àti àwọn Gísì àti àwọn ọmọ Ámálékì,+ nítorí wọ́n ń gbé ilẹ̀ tí ó lọ láti Télámù títí dé Ṣúrì+ àti títí dé ilẹ̀ Íjíbítì. 9 Nígbà tí Dáfídì bá lọ gbéjà ko ilẹ̀ náà, kì í dá ọkùnrin tàbí obìnrin sí,+ àmọ́ á kó àwọn agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti ràkúnmí àti aṣọ, lẹ́yìn náà, á wá pa dà sọ́dọ̀ Ákíṣì.
-
-
1 Sámúẹ́lì 30:18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Dáfídì gba gbogbo ohun tí àwọn ọmọ Ámálékì ti kó pa dà,+ Dáfídì sì gba ìyàwó rẹ̀ méjèèjì sílẹ̀.
-
-
1 Sámúẹ́lì 30:20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Torí náà, Dáfídì kó gbogbo agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran náà, èyí tí wọ́n ń dà lọ níwájú àwọn ẹran ọ̀sìn tiwọn. Wọ́n sọ pé: “Ẹrù tí Dáfídì kó nìyí.”
-