7 Igi ọ̀kọ̀ rẹ̀ dà bí ọ̀pá àwọn ahunṣọ,*+ ìwọ̀n irin tí wọ́n fi ṣe aṣóró ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ṣékélì;* ẹni tó ń bá a gbé apata sì ń lọ níwájú rẹ̀.
9 Àlùfáà náà bá sọ pé: “Idà Gòláyátì+ ará Filísínì tí o pa ní Àfonífojì* Élà+ wà níbí, òun ni wọ́n faṣọ wé lẹ́yìn éfódì+ yẹn. Tí o bá fẹ́ mú un, o lè mú un, torí òun nìkan ló wà níbí.” Dáfídì wá sọ pé: “Kò sí èyí tó dà bíi rẹ̀. Mú un fún mi.”