-
1 Kíróníkà 16:41, 42Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
41 Àwọn tó wà pẹ̀lú wọn ni Hémánì àti Jédútúnì+ pẹ̀lú ìyókù àwọn ọkùnrin tí a fi orúkọ yàn láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà,+ nítorí “ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé”;+ 42 Hémánì+ àti Jédútúnì wà pẹ̀lú wọn láti máa fun kàkàkí, láti máa lo síńbálì àti àwọn ohun ìkọrin tí a fi ń yin* Ọlọ́run tòótọ́; àwọn ọmọ Jédútúnì+ sì wà ní ẹnubodè.
-
-
2 Kíróníkà 5:11, 12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Nígbà tí àwọn àlùfáà jáde láti ibi mímọ́ (nítorí gbogbo àwọn àlùfáà tó wà níbẹ̀ ni wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́,+ láìka àwùjọ tí wọ́n wà sí),+ 12 gbogbo àwọn ọmọ Léfì tó jẹ́ akọrin+ tí wọ́n jẹ́ ti Ásáfù,+ ti Hémánì,+ ti Jédútúnì + àti ti àwọn ọmọ wọn àti àwọn arákùnrin wọn ló wọ aṣọ àtàtà, síńbálì* wà lọ́wọ́ wọn àti àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù; wọ́n dúró sí apá ìlà oòrùn pẹpẹ, àwọn pẹ̀lú ọgọ́fà (120) àlùfáà tó ń fun kàkàkí.+
-