2 Nítorí náà, ọba sọ fún Jóábù+ olórí àwọn ọmọ ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, lọ yí ká gbogbo àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, láti Dánì títí dé Bíá-ṣébà,+ kí ẹ sì forúkọ àwọn èèyàn náà sílẹ̀, kí n lè mọ iye wọn.”
15 Nígbà náà, Jèhófà rán àjàkálẹ̀ àrùn+ sí Ísírẹ́lì láti àárọ̀ títí di àkókò tó dá, tí ọ̀kẹ́ mẹ́ta ààbọ̀ (70,000) fi kú+ lára àwọn èèyàn náà láti Dánì títí dé Bíá-ṣébà.+