-
2 Àwọn Ọba 21:2-6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Ó ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà, torí pé ó ń ṣe àwọn ohun ìríra bíi ti àwọn orílẹ̀-èdè+ tí Jèhófà lé kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 3 Ó tún àwọn ibi gíga kọ́, èyí tí Hẹsikáyà bàbá rẹ̀ pa run,+ ó mọ àwọn pẹpẹ fún Báálì, ó sì ṣe òpó òrìṣà,*+ bí Áhábù ọba Ísírẹ́lì ti ṣe.+ Ó forí balẹ̀ fún gbogbo ọmọ ogun ọ̀run, ó sì ń sìn wọ́n.+ 4 Ó tún mọ àwọn pẹpẹ sí ilé Jèhófà,+ níbi tí Jèhófà sọ nípa rẹ̀ pé: “Inú Jerúsálẹ́mù ni màá fi orúkọ mi sí.”+ 5 Ó mọ àwọn pẹpẹ fún gbogbo ọmọ ogun ọ̀run+ sí àgbàlá méjì nínú ilé Jèhófà.+ 6 Ó sun ọmọ rẹ̀ nínú iná; ó ń pidán, ó ń woṣẹ́,+ ó sì yan àwọn abẹ́mìílò àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́.+ Ohun búburú tó pọ̀ gan-an ló ṣe lójú Jèhófà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú un bínú.
-