-
2 Àwọn Ọba 21:19-24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Ẹni ọdún méjìlélógún (22) ni Ámọ́nì+ nígbà tó jọba, ọdún méjì ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Méṣúlémétì ọmọ Hárúsì láti Jótíbà. 20 Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà bí Mánásè bàbá rẹ̀ ti ṣe.+ 21 Ó ń rìn ní gbogbo ọ̀nà tí bàbá rẹ̀ rìn, ó ń sin àwọn òrìṣà ẹ̀gbin tí bàbá rẹ̀ sìn, ó sì ń forí balẹ̀ fún wọn.+ 22 Torí náà, ó fi Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ̀ sílẹ̀, kò sì rìn ní ọ̀nà Jèhófà.+ 23 Níkẹyìn, àwọn ìránṣẹ́ Ámọ́nì dìtẹ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì pa á nínú ilé rẹ̀. 24 Àmọ́ àwọn èèyàn ilẹ̀ náà pa gbogbo àwọn tó dìtẹ̀ mọ́ Ọba Ámọ́nì, wọ́n sì fi Jòsáyà ọmọ rẹ̀ jọba ní ipò rẹ̀.+
-