19 Jòsáyà tún mú gbogbo àwọn ilé ìjọsìn tó wà lórí àwọn ibi gíga kúrò ní àwọn ìlú Samáríà,+ èyí tí àwọn ọba Ísírẹ́lì kọ́ láti mú Ọlọ́run bínú, ohun tó ṣe ní Bẹ́tẹ́lì ló ṣe sí àwọn náà.+
30Hẹsikáyà ránṣẹ́ sí gbogbo Ísírẹ́lì+ àti Júdà, ó tiẹ̀ tún kọ lẹ́tà sí Éfúrémù àti Mánásè,+ pé kí wọ́n wá sí ilé Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù láti wá ṣe Ìrékọjá sí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+