24 Gbàrà tí Mósè kọ gbogbo ọ̀rọ̀ Òfin yìí sínú ìwé tán,+25 Mósè pàṣẹ fún àwọn ọmọ Léfì tó ń gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà, pé: 26 “Ẹ gba ìwé Òfin yìí,+ kí ẹ fi sí ẹ̀gbẹ́ àpótí+ májẹ̀mú Jèhófà Ọlọ́run yín, kó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí lòdì sí yín níbẹ̀.
8 Ìwé Òfin yìí kò gbọ́dọ̀ kúrò ní ẹnu rẹ,+ kí o máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kà á* tọ̀sántòru, kí o lè rí i pé ò ń tẹ̀ lé gbogbo ohun tí wọ́n kọ sínú rẹ̀;+ ìgbà yẹn ni ọ̀nà rẹ máa yọrí sí rere, tí wàá sì máa hùwà ọgbọ́n.+
8 Lẹ́yìn náà, Hilikáyà àlùfáà àgbà sọ fún Ṣáfánì akọ̀wé+ pé: “Mo ti rí ìwé Òfin+ ní ilé Jèhófà.” Torí náà, Hilikáyà fún Ṣáfánì ní ìwé náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á.+