7Gbàrà tí Sólómọ́nì parí àdúrà rẹ̀,+ iná bọ́ láti ọ̀run,+ ó jó ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ náà, ògo Jèhófà sì kún ilé náà.+2 Àwọn àlùfáà kò lè wọnú ilé Jèhófà nítorí pé ògo Jèhófà ti kún ilé Jèhófà.+
4 Ògo Jèhófà+ gbéra láti orí àwọn kérúbù wá sí ẹnu ọ̀nà ilé náà, ìkùukùu sì bẹ̀rẹ̀ sí í kún inú ilé náà díẹ̀díẹ̀,+ ògo Jèhófà sì mọ́lẹ̀ yòò ní gbogbo àgbàlá náà.