-
Diutarónómì 7:9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 O mọ̀ dáadáa pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni Ọlọ́run tòótọ́, Ọlọ́run tó ṣeé fọkàn tán, tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́, tó sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn títí dé ẹgbẹ̀rún ìran àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.+
-
-
1 Àwọn Ọba 8:23-26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 ó sì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kò sí Ọlọ́run tó dà bí rẹ+ ní ọ̀run lókè tàbí lórí ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀, ò ń pa májẹ̀mú mọ́, o sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀+ hàn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ tó ń fi gbogbo ọkàn wọn rìn níwájú rẹ.+ 24 O ti mú ìlérí tí o ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì bàbá mi ṣẹ. Ẹnu rẹ lo fi ṣe ìlérí náà, o sì ti fi ọwọ́ ara rẹ mú un ṣẹ lónìí yìí.+ 25 Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, mú ìlérí tí o ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì bàbá mi ṣẹ, nígbà tí o sọ pé: ‘Kò ní ṣàìsí ọkùnrin kan láti ìlà ìdílé rẹ níwájú mi tí yóò máa jókòó sórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì, bí àwọn ọmọ rẹ bá ṣáà ti ń fiyè sí ọ̀nà wọn, tí wọ́n sì ń rìn níwájú mi bí ìwọ náà ṣe rìn níwájú mi.’+ 26 Ní báyìí, ìwọ Ọlọ́run Ísírẹ́lì, jọ̀wọ́ mú ìlérí tí o ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì bàbá mi ṣẹ.
-