ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Àwọn Ọba 10:4-9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Nígbà tí ọbabìnrin Ṣébà rí gbogbo ọgbọ́n Sólómọ́nì+ àti ilé tó kọ́,+ 5 oúnjẹ orí tábìlì rẹ̀,+ bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ń jókòó, bó ṣe ṣètò iṣẹ́ àwọn tó ń gbé oúnjẹ fún un àti aṣọ tí wọ́n ń wọ̀, àwọn agbọ́tí rẹ̀ àti àwọn ẹbọ sísun tó ń rú déédéé ní ilé Jèhófà, ẹnu yà á gan-an.* 6 Nítorí náà, ó sọ fún ọba pé: “Òótọ́ ni ìròyìn tí mo gbọ́ ní ilẹ̀ mi nípa àwọn àṣeyọrí* rẹ àti ọgbọ́n rẹ. 7 Àmọ́ mi ò gba ìròyìn náà gbọ́ títí mo fi wá fojú ara mi rí i. Wò ó! Ohun tí mo gbọ́ kò tiẹ̀ tó ìdajì rárá. Ọgbọ́n rẹ àti aásìkí rẹ kọjá àwọn ohun tí mo gbọ́. 8 Aláyọ̀ ni àwọn èèyàn rẹ, aláyọ̀ sì ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wọ́n ń dúró níwájú rẹ nígbà gbogbo, tí wọ́n ń fetí sí ọgbọ́n rẹ!+ 9 Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí ọ tí ó fi gbé ọ gorí ìtẹ́ Ísírẹ́lì. Nítorí ìfẹ́ àìnípẹ̀kun tí Jèhófà ní sí Ísírẹ́lì, ó fi ọ́ jọba láti máa dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́ àti láti máa ṣe òdodo.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́