-
1 Kíróníkà 22:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Nígbà náà, Dáfídì sọ pé: “Ilé Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ nìyí, pẹpẹ ẹbọ sísun fún Ísírẹ́lì sì nìyí.”+
-
-
2 Kíróníkà 15:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Gbàrà tí Ásà gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí àti àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Ódédì, ó mọ́kàn le, ó sì mú àwọn òrìṣà ẹ̀gbin kúrò ní gbogbo ilẹ̀ Júdà+ àti Bẹ́ńjámínì àti ní àwọn ìlú tó gbà ní agbègbè olókè Éfúrémù, ó tún pẹpẹ Jèhófà tó wà níwájú ibi tí wọ́n ń gbà wọ* ilé Jèhófà mọ.+ 9 Ó kó gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì jọ pẹ̀lú àwọn àjèjì tó wà pẹ̀lú wọn tí wọ́n wá láti Éfúrémù àti Mánásè àti Síméónì,+ torí ọ̀pọ̀ wọn ló sá wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n rí i pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.
-