-
Àwọn Onídàájọ́ 9:5, 6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ilé bàbá rẹ̀ ní Ọ́fírà,+ ó sì pa àwọn arákùnrin rẹ̀,+ àwọn ọmọ Jerubáálì, àádọ́rin (70) ọkùnrin, lórí òkúta kan. Jótámù, ọmọ Jerubáálì tó kéré jù nìkan ló ṣẹ́ kù, torí pé ó sá pa mọ́.
6 Gbogbo àwọn olórí Ṣékémù àti gbogbo Bẹti-mílò wá kóra jọ, wọ́n sì fi Ábímélékì jọba,+ nítòsí igi ńlá, lẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó* tó wà ní Ṣékémù.
-