12 Nígbà tí o bá kú,+ tí o sì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ, nígbà náà, màá gbé ọmọ* rẹ dìde lẹ́yìn rẹ, ọmọ ìwọ fúnra rẹ,* màá sì fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀.+13 Òun ló máa kọ́ ilé fún orúkọ mi,+ màá sì fìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.+
4 Àmọ́, nítorí Dáfídì,+ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ jẹ́ kí àtọmọdọ́mọ rẹ̀ máa ṣàkóso* ní Jerúsálẹ́mù,+ ó gbé ọmọ rẹ̀ dìde lẹ́yìn rẹ̀, ó sì jẹ́ kí Jerúsálẹ́mù máa wà nìṣó.