-
2 Àwọn Ọba 11:5-8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Ó pàṣẹ fún wọn pé: “Ohun tí ẹ máa ṣe nìyí: Ìdá mẹ́ta yín á wà lẹ́nu iṣẹ́ ní Sábáàtì, ẹ ó sì máa ṣọ́ ilé* ọba+ lójú méjèèjì, 6 ìdá mẹ́ta míì á wà ní Ẹnubodè Ìpìlẹ̀, ìdá mẹ́ta míì á sì wà ní ẹnubodè tó wà lẹ́yìn àwọn ẹ̀ṣọ́ ààfin. Kí ẹ máa ṣe iṣẹ́ ṣíṣọ́ ilé náà ní àṣegbà. 7 Ìdá méjì tí kò ní sí lẹ́nu iṣẹ́ ní ọjọ́ Sábáàtì ní láti máa ṣọ́ ilé Jèhófà lójú méjèèjì láti dáàbò bo ọba. 8 Kí ẹ yí ọba ká, kálukú pẹ̀lú àwọn ohun ìjà rẹ̀ lọ́wọ́. Ẹni tó bá wọlé wá sáàárín àwọn ọmọ ogun ni a ó pa. Ẹ dúró ti ọba níbikíbi tó bá lọ.”*
-
-
1 Kíróníkà 9:22-25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Gbogbo àwọn tí wọ́n yàn ṣe aṣọ́bodè ní àwọn ibi àbáwọlé jẹ́ igba ó lé méjìlá (212). Wọ́n wà ní ibi tí wọ́n tẹ̀ dó sí bí orúkọ wọn ṣe wà nínú àkọsílẹ̀ ìdílé wọn.+ Dáfídì àti Sámúẹ́lì aríran+ ló yàn wọ́n sí ipò ẹni tó ṣeé fọkàn tán tí wọ́n wà. 23 Àwọn àti àwọn ọmọ wọn ló ń ṣọ́ àwọn ẹnubodè ilé Jèhófà,+ ìyẹn ilé àgọ́. 24 Àwọn aṣọ́bodè wà ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, ìyẹn ní ìlà oòrùn, ìwọ̀ oòrùn, àríwá àti gúúsù.+ 25 Látìgbàdégbà, àwọn arákùnrin wọn máa ń wá láti àwọn ibi tí wọ́n tẹ̀ dó sí láti bá wọn ṣiṣẹ́ fún ọjọ́ méje.
-