-
1 Kíróníkà 26:26, 27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Ṣẹ́lómótì yìí àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ló ń bójú tó gbogbo àwọn ibi ìṣúra tí wọ́n ń kó àwọn ohun tí a sọ di mímọ́+ sí, tí Ọba Dáfídì+ àti àwọn olórí agbo ilé+ àti àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti ti ọgọ́rọ̀ọ̀rún pẹ̀lú àwọn olórí ọmọ ogun ti sọ di mímọ́. 27 Lára àwọn ẹrù + tí wọ́n kó lójú ogun,+ wọ́n ya àwọn ohun kan sí mímọ́ láti máa fi tọ́jú ilé Jèhófà;
-