-
2 Àwọn Ọba 12:4, 5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Jèhóáṣì sọ fún àwọn àlùfáà pé: “Ẹ gba gbogbo owó tó jẹ́ ọrẹ mímọ́+ tí wọ́n bá mú wá sí ilé Jèhófà, ìyẹn owó tí wọ́n ní kí ẹnì kọ̀ọ̀kan mú wá,+ owó tí àwọn àlùfáà gbà lọ́wọ́ àwọn* tó jẹ́ ẹ̀jẹ́ àti gbogbo owó tó bá wá látọkàn kálukú láti mú wá sí ilé Jèhófà.+ 5 Àwọn àlùfáà yóò fúnra wọn gbà á lọ́wọ́ àwọn tó ń dáwó fún wọn,* wọ́n á sì lò ó láti fi ṣàtúnṣe ibikíbi tí wọ́n bá rí pé ó bà jẹ́* lára ilé náà.”+
-
-
2 Kíróníkà 29:3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Ní ọdún kìíní ìjọba rẹ̀, ní oṣù kìíní, ó ṣí àwọn ilẹ̀kùn ilé Jèhófà, ó sì tún wọn ṣe.+
-
-
2 Kíróníkà 34:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Wọ́n wá sọ́dọ̀ Hilikáyà àlùfáà àgbà, wọ́n sì fún un ní owó tí àwọn èèyàn mú wá sí ilé Ọlọ́run, èyí tí àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ aṣọ́nà ti gbà lọ́wọ́ Mánásè àti Éfúrémù àti lọ́wọ́ gbogbo ìyókù Ísírẹ́lì,+ títí kan Júdà, Bẹ́ńjámínì àti àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù. 10 Lẹ́yìn náà, wọ́n kó o fún àwọn tí wọ́n yàn láti máa bójú tó iṣẹ́ ilé Jèhófà. Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ilé Jèhófà sì lò ó láti mú ilé náà bọ̀ sípò àti láti tún un ṣe.
-