-
2 Kíróníkà 17:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Wọ́n pín wọn sí agbo ilé àwọn bàbá wọn: nínú àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún látinú Júdà, àkọ́kọ́ ni Ádínáhì olórí, ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (300,000) jagunjagun tó lákíkanjú sì wà pẹ̀lú rẹ̀.+
-
-
2 Kíróníkà 25:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Amasááyà wá kó gbogbo Júdà jọ, ó sì ní kí wọ́n dúró ní agboolé-agboolé, sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún ní gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì.+ Ó forúkọ wọn sílẹ̀ láti ẹni ogún (20) ọdún sókè,+ ó rí i pé wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300,000) akọgun* tó ń ṣiṣẹ́ ológun, tí wọ́n sì lè lo aṣóró àti apata ńlá.
-