15 Torí náà, Hẹsikáyà fi gbogbo fàdákà tí wọ́n rí ní ilé Jèhófà àti ní àwọn ibi ìṣúra ilé ọba+ lélẹ̀. 16 Lákòókò yẹn, Hẹsikáyà yọ àwọn ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì+ Jèhófà kúrò àti àwọn òpó ilẹ̀kùn tí Hẹsikáyà ọba Júdà fúnra rẹ̀ fi wúrà bò,+ ó sì kó wọn fún ọba Ásíríà.