-
Léfítíkù 3:14-16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Ibi tó máa fi ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà lára ẹran náà ni ọ̀rá tó bo ìfun, gbogbo ọ̀rá tó yí ìfun ká,+ 15 pẹ̀lú kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá tó wà lára wọn nítòsí abẹ́nú. Kó tún yọ àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀ pẹ̀lú àwọn kíndìnrín rẹ̀. 16 Kí àlùfáà mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ bí oúnjẹ, ọrẹ àfinásun tó máa mú òórùn dídùn* jáde ló jẹ́. Ti Jèhófà ni gbogbo ọ̀rá.+
-