-
Nọ́ńbà 9:10, 11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ẹnikẹ́ni nínú yín tàbí nínú àwọn ìran yín tó ń bọ̀ bá di aláìmọ́ torí pé ó fara kan òkú èèyàn*+ tàbí tí ó rin ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn, ẹni náà ṣì gbọ́dọ̀ ṣètò ẹbọ Ìrékọjá fún Jèhófà. 11 Kí wọ́n ṣètò rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́* ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejì.+ Kí wọ́n jẹ ẹ́ pẹ̀lú búrẹ́dì aláìwú àti ewébẹ̀ kíkorò.+
-