-
Ẹ́sírà 6:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Ìgbà náà ni Ọba Dáríúsì pa àṣẹ kan, wọ́n sì ṣe àyẹ̀wò nínú ibi ìkówèésí* tó wà ní àwọn ibi tí wọ́n ń kó ìṣúra sí ní Bábílónì.
-
-
Hágáì 1:14, 15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Torí náà, Jèhófà ru ẹ̀mí+ Serubábélì ọmọ Ṣéálítíẹ́lì, gómìnà Júdà+ sókè, ó tún ru ẹ̀mí Jóṣúà+ ọmọ Jèhósádákì, àlùfáà àgbà sókè àti ẹ̀mí gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù nínú àwọn èèyàn náà; wọ́n wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àtúnkọ́ ilé Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun tó jẹ́ Ọlọ́run wọn.+ 15 Èyí jẹ́ ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹfà ní ọdún kejì tí Ọba Dáríúsì ń ṣàkóso.+
-