ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́sírà 6:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Àwọn àgbààgbà Júù ń bá iṣẹ́ ìkọ́lé náà lọ, wọ́n ń tẹ̀ síwájú,+ àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Hágáì+ àti Sekaráyà+ ọmọ ọmọ Ídò sì ń fún wọn níṣìírí; wọ́n parí iṣẹ́ ìkọ́lé náà nípa àṣẹ Ọlọ́run Ísírẹ́lì+ àti nípa àṣẹ Kírúsì+ àti Dáríúsì+ àti Atasásítà+ ọba Páṣíà.

  • Hágáì 2:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 “‘Àmọ́ ní báyìí, ìwọ Serubábélì, jẹ́ onígboyà. Kí ìwọ Jóṣúà ọmọ Jèhósádákì, àlùfáà àgbà pẹ̀lú sì jẹ́ onígboyà,’ ni Jèhófà wí.

      “‘Kí gbogbo ẹ̀yin èèyàn ilẹ̀ náà pẹ̀lú jẹ́ onígboyà,+ kí ẹ sì ṣiṣẹ́’ ni Jèhófà wí.

      “‘Torí mo wà pẹ̀lú yín,’+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.

  • Hágáì 2:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 “Sọ fún Serubábélì, gómìnà Júdà pé, ‘Èmi yóò mi ọ̀run àti ayé jìgìjìgì.+

  • Sekaráyà 4:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Báwo ni tìẹ ṣe jẹ́ ìwọ òkè ńlá? Wàá di ilẹ̀ pẹrẹsẹ*+ níwájú Serubábélì.+ Òun yóò mú òkúta tó wà lókè jáde bí àwọn èèyàn ṣe ń kígbe pé: “Ó mà dára o! Ó mà dára o!”’”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́