14 Torí náà, Jèhófà ru ẹ̀mí+ Serubábélì ọmọ Ṣéálítíẹ́lì, gómìnà Júdà+ sókè, ó tún ru ẹ̀mí Jóṣúà+ ọmọ Jèhósádákì, àlùfáà àgbà sókè àti ẹ̀mí gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù nínú àwọn èèyàn náà; wọ́n wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àtúnkọ́ ilé Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun tó jẹ́ Ọlọ́run wọn.+