3 “‘Tó bá fẹ́ mú ẹran wá láti fi rú ẹbọ sísun látinú ọ̀wọ́ ẹran, kó jẹ́ akọ tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá.+ Tinútinú+ ni kó mú un wá síwájú Jèhófà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.
5 “‘Lẹ́yìn náà, kí wọ́n pa akọ màlúù náà níwájú Jèhófà, àwọn ọmọ Áárónì, tí wọ́n jẹ́ àlùfáà,+ yóò sì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá, wọ́n á wọ́n ọn sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà,+ èyí tó wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.