31 Àwọn tí Dáfídì yàn pé kí wọ́n máa darí orin ní ilé Jèhófà lẹ́yìn tí wọ́n gbé Àpótí náà síbẹ̀ nìyí.+ 32 Ojúṣe wọn ni láti máa kọrin ní àgọ́ ìjọsìn, ìyẹn ni àgọ́ ìpàdé títí di ìgbà tí Sólómọ́nì kọ́ ilé Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù,+ wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún wọn bí wọ́n ṣe ni kí wọ́n máa ṣe é.+