-
Ẹ́sírà 1:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
1 Ní ọdún kìíní Kírúsì+ ọba Páṣíà, kí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Jeremáyà+ sọ lè ṣẹ, Jèhófà ta ẹ̀mí Kírúsì ọba Páṣíà jí láti kéde ní gbogbo ìjọba rẹ̀, ó sì tún kọ ọ́ sílẹ̀+ pé:
2 “Ohun tí Kírúsì ọba Páṣíà sọ nìyí, ‘Jèhófà Ọlọ́run ọ̀run ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé,+ ó sì pàṣẹ fún mi pé kí n kọ́ ilé fún òun ní Jerúsálẹ́mù,+ tó wà ní Júdà. 3 Ta ni nínú yín tó jẹ́ èèyàn rẹ̀? Kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó lọ sí Jerúsálẹ́mù tó wà ní Júdà, kí ó sì tún ilé Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì kọ́, òun ni Ọlọ́run tòótọ́, tí ilé rẹ̀ wà ní Jerúsálẹ́mù.*
-