-
Ẹ́sírà 4:6-8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Ahasuérúsì, wọ́n kọ̀wé ẹ̀sùn mọ́ àwọn tó ń gbé Júdà àti Jerúsálẹ́mù. 7 Nígbà ayé Atasásítà ọba Páṣíà, Bíṣílámù, Mítírédátì, Tábéélì àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù kọ̀wé sí Ọba Atasásítà; wọ́n túmọ̀ lẹ́tà náà sí èdè Árámáíkì,+ ọ̀nà ìkọ̀wé èdè Árámáíkì ni wọ́n sì fi kọ ọ́.*
8 * Réhúmù olórí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àti Ṣímúṣáì akọ̀wé òfin kọ lẹ́tà kan mọ́ Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí Ọba Atasásítà, lẹ́tà náà kà pé:
-