-
Nehemáyà 2:19, 20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Nígbà tí Sáńbálátì ará Hórónì àti Tòbáyà + ọmọ Ámónì+ tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ọba* pẹ̀lú Géṣémù ọmọ ilẹ̀ Arébíà+ gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi wá ṣe yẹ̀yẹ́,+ wọ́n sì ń fojú pa wá rẹ́, wọ́n ní: “Kí lẹ̀ ń ṣe yìí? Ẹ fẹ́ ṣọ̀tẹ̀ sí ọba, àbí?”+ 20 Àmọ́, mo fún wọn lésì pé: “Ọlọ́run ọ̀run ni Ẹni tó máa jẹ́ ká ṣàṣeyọrí,+ àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò dìde, a ó sì kọ́lé; àmọ́ ẹ̀yin ò ní ìpín kankan, bẹ́ẹ̀ ni ẹ ò ní ẹ̀tọ́ tàbí ìrántí ní Jerúsálẹ́mù.”+
-