20 Tí mo bá mú wọn dé ilẹ̀ tí mo búra nípa rẹ̀ fún àwọn baba ńlá wọn,+ ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn,+ tí wọ́n jẹun tẹ́rùn, tí nǹkan sì ń lọ dáadáa fún wọn,*+ wọ́n á lọ máa tọ àwọn ọlọ́run míì lẹ́yìn, wọ́n á sì máa sìn wọ́n, wọ́n á hùwà àfojúdi sí mi, wọ́n á sì da májẹ̀mú mi.+
12 Bí wọ́n ṣe fi Jèhófà, Ọlọ́run àwọn bàbá wọn sílẹ̀ nìyẹn, ẹni tó mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Wọ́n wá tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì, àwọn ọlọ́run àwọn èèyàn tó yí wọn ká,+ wọ́n forí balẹ̀ fún wọn, wọ́n sì múnú bí Jèhófà.+