8 Ààlà náà dé Àfonífojì Ọmọ Hínómù,+ ó dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àwọn ará Jébúsì+ ní gúúsù, ìyẹn Jerúsálẹ́mù,+ ààlà náà dé orí òkè tó dojú kọ Àfonífojì Hínómù lápá ìwọ̀ oòrùn, èyí tó wà ní ìkángun Àfonífojì* Réfáímù lápá àríwá.
10 Ó tún sọ Tófétì+ tó wà ní Àfonífojì Àwọn Ọmọ Hínómù*+ di ibi tí kò ṣeé lò fún ìjọsìn, kí ẹnikẹ́ni má bàa sun ọmọkùnrin rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ nínú iná sí Mólékì.+