-
Diutarónómì 23:3, 4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 “Ọmọ Ámónì tàbí ọmọ Móábù kankan ò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà.+ Àní títí dé ìran wọn kẹwàá, àtọmọdọ́mọ wọn kankan ò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà láé, 4 torí pé wọn ò fún yín ní oúnjẹ àti omi láti fi ràn yín lọ́wọ́ nígbà tí ẹ kúrò ní Íjíbítì,+ wọ́n sì tún gba Báláámù ọmọ Béórì láti Pétórì ti Mesopotámíà pé kó wá gégùn-ún fún* yín.+
-
-
Ẹ́sírà 9:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Gbàrà tí a parí àwọn nǹkan yìí, àwọn olórí wá bá mi, wọ́n sì sọ pé: “Àwọn èèyàn Ísírẹ́lì àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì kò ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn èèyàn àwọn ilẹ̀ tó yí wọn ká àti àwọn ohun ìríra wọn,+ ìyẹn àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Pérísì, àwọn ará Jébúsì, àwọn ọmọ Ámónì, àwọn ọmọ Móábù, àwọn ará Íjíbítì+ àti àwọn Ámórì. + 2 Wọ́n ti fi lára àwọn ọmọbìnrin wọn ṣe aya, wọ́n sì tún fẹ́ wọn fún àwọn ọmọkùnrin wọn.+ Ní báyìí, àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ* mímọ́+ ti dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn àwọn ilẹ̀ tó yí wọn ká.+ Àwọn olórí àti àwọn alábòójútó sì ni òléwájú nínú ìwà àìṣòótọ́ yìí.”
-
-
Ẹ́sírà 10:10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Nígbà náà, àlùfáà Ẹ́sírà dìde, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ ti hùwà àìṣòótọ́ bí ẹ ṣe lọ ń fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì,+ ẹ sì ti dá kún ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì.
-