5 Ọkùnrin Júù kan wà ní Ṣúṣánì+ ilé ńlá, Módékáì+ lorúkọ rẹ̀, ó jẹ́ ọmọ Jáírì, ọmọ Ṣíméì, ọmọ Kíṣì, ọmọ Bẹ́ńjámínì,+ 6 ẹni tí wọ́n mú láti Jerúsálẹ́mù lọ sí ìgbèkùn pẹ̀lú àwọn èèyàn tí wọ́n kó mọ́ Jekonáyà+ ọba Júdà, tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì mú lọ sí ìgbèkùn.