10 Àwọn tó ń gbé ìlànà tó ń pani lára kalẹ̀ gbé,+
Àwọn tó ń ṣe òfin tó ń nini lára ṣáá,
2 Láti fi ẹ̀tọ́ àwọn aláìní dù wọ́n lábẹ́ òfin,
Láti fi ìdájọ́ òdodo du àwọn tó rẹlẹ̀ láàárín àwọn èèyàn mi,+
Wọ́n ń kó àwọn opó nífà bí ẹrù ogun
Àti àwọn ọmọ aláìníbaba bí ẹrù tí wọ́n kó lójú ogun!+
3 Kí lẹ máa ṣe ní ọjọ́ ìjíhìn,+
Tí ìparun bá wá láti ọ̀nà jíjìn?+
Ta lẹ máa sá lọ bá pé kó ràn yín lọ́wọ́,+
Ibo lẹ sì máa fi ọrọ̀ yín sí?