15 Tí arákùnrin tàbí arábìnrin èyíkéyìí ò bá láṣọ,* tí wọn ò sì ní oúnjẹ tó máa tó wọn jẹ lóòjọ́, 16 síbẹ̀ tí ẹnì kan nínú yín sọ fún wọn pé, “Ẹ máa lọ ní àlàáfíà; kí ẹ rí aṣọ fi bora, kí ẹ sì yó dáadáa,” àmọ́ tí ẹ ò fún wọn ní ohun tí ara wọn nílò, àǹfààní kí ló jẹ́?+