ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 20:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 “O ò gbọ́dọ̀ lo orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ lọ́nà tí kò tọ́,+ torí Jèhófà kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹni tó bá lo orúkọ Rẹ̀ lọ́nà tí kò tọ́.+

  • Jóòbù 4:18-20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Wò ó! Kò ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,

      Ó sì ń wá àṣìṣe àwọn áńgẹ́lì* rẹ̀.

      19 Mélòómélòó wá ni àwọn tó ń gbé ilé alámọ̀,

      Tí ìpìlẹ̀ wọn wà nínú iyẹ̀pẹ̀,+

      Tí wọ́n rọrùn láti tẹ̀ rẹ́ bí òólá!*

      20 A tẹ̀ wọ́n rẹ́ pátápátá láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀;

      Wọ́n ṣègbé títí láé, ẹnì kankan ò sì kíyè sí i.

  • Jóòbù 22:2, 3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  2 “Ṣé èèyàn wúlò fún Ọlọ́run?

      Ṣé ẹni tó ní ìjìnlẹ̀ òye lè ṣe é láǹfààní?+

       3 Tí o bá jẹ́ olódodo, kí ló kan Olódùmarè,*

      Àbí ó jèrè kankan torí pé o rìn ní ọ̀nà ìwà títọ́?+

  • Jóòbù 25:5, 6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  5 Òṣùpá pàápàá kò mọ́lẹ̀,

      Àwọn ìràwọ̀ ò sì mọ́ lójú rẹ̀,

       6 Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti ẹni kíkú, tó jẹ́ ìdin

      Àti ọmọ èèyàn, tó jẹ́ kòkòrò mùkúlú!”

  • Jóòbù 42:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Ó yá, ẹ mú akọ màlúù méje àti àgbò méje, kí ẹ lọ bá Jóòbù ìránṣẹ́ mi, kí ẹ sì rú ẹbọ sísun fún ara yín. Jóòbù ìránṣẹ́ mi sì máa gbàdúrà fún yín.+ Ó dájú pé màá gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀* pé kí n má fìyà jẹ yín nítorí ìwà òmùgọ̀ yín, torí ẹ ò sọ òtítọ́ nípa mi, bí ìránṣẹ́ mi Jóòbù ṣe sọ òtítọ́.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́