ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 139:11, 12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Tí mo bá sọ pé: “Dájúdájú, òkùnkùn yóò fi mí pa mọ́!”

      Nígbà náà, òkùnkùn tó yí mi ká yóò di ìmọ́lẹ̀.

      12 Kódà, òkùnkùn náà kò ní ṣú jù fún ọ,

      Ṣe ni òru yóò mọ́lẹ̀ bí ọ̀sán;+

      Ìkan náà ni òkùnkùn àti ìmọ́lẹ̀ lójú rẹ.+

  • Àìsáyà 29:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Ó mà ṣe o, fún àwọn tó sapá gidigidi kí wọ́n lè fi ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe* pa mọ́ fún Jèhófà.+

      Ibi tó ṣókùnkùn ni wọ́n ti ṣe iṣẹ́ wọn,

      Tí wọ́n ń sọ pé: “Ta ló rí wa,

      Ta ló mọ̀ nípa wa?”+

  • Jeremáyà 23:24
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 “Ṣé ibì kan wà téèyàn lè sá pa mọ́ sí tí mi ò ní lè rí i?”+ ni Jèhófà wí.

      “Ǹjẹ́ ohunkóhun wà láyé tàbí lọ́run tí ojú mi ò tó?”+ ni Jèhófà wí.

  • Émọ́sì 9:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  3 Bí wọ́n bá fara pa mọ́ sórí òkè Kámẹ́lì,

      Ibẹ̀ ni màá ti wá wọn kàn, màá sì mú wọn.+

      Bí wọ́n bá sì fara pa mọ́ kúrò ní ojú mi ní ìsàlẹ̀ òkun,

      Ibẹ̀ ni màá ti pàṣẹ fún ejò, á sì bù wọ́n ṣán.

  • Hébérù 4:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Kò sí ìṣẹ̀dá kankan tó fara pa mọ́ ní ojú rẹ̀,+ àmọ́ ohun gbogbo wà ní ìhòòhò, ó sì wà ní gbangba lójú ẹni tí a gbọ́dọ̀ jíhìn fún.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́