19 Mikáyà bá sọ pé: “Nítorí náà, gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà: Mo rí Jèhófà tó jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀,+ gbogbo ọmọ ogun ọ̀run sì dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, lápá ọ̀tún àti lápá òsì.+
13 “Mò ń wò nínú ìran òru, sì wò ó! ẹnì kan bí ọmọ èèyàn+ ń bọ̀ pẹ̀lú ìkùukùu* ojú ọ̀run; a jẹ́ kó wọlé wá sọ́dọ̀ Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé,+ wọ́n sì mú un wá sún mọ́ iwájú Ẹni yẹn.