6 Bákan náà, láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run dáadáa, torí ẹnikẹ́ni tó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó wà àti pé òun ló ń san èrè fún àwọn tó ń wá a tọkàntọkàn.+
11 Ẹ wò ó! A ka àwọn tó ní ìfaradà sí aláyọ̀.*+ Ẹ ti gbọ́ nípa ìfaradà Jóòbù,+ ẹ sì ti rí ibi tí Jèhófà* jẹ́ kó yọrí sí,+ pé Jèhófà* ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tó pọ̀ gan-an,* ó sì jẹ́ aláàánú.+